5. Emi duro dè Oluwa, ọkàn mi duro, ati ninu ọ̀rọ rẹ̀ li emi nṣe ireti.
6. Ọkàn mi duro dè Oluwa, jù awọn ti nṣọ́na owurọ lọ, ani jù awọn ti nṣọ́na owurọ lọ.
7. Israeli iwọ ni ireti niti Oluwa: nitori pe lọdọ Oluwa li ãnu wà, ati lọdọ rẹ̀ li ọ̀pọlọpọ idande wà.
8. On o si da Israeli nidè kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo,