1. LATI inu ibu wá li emi kepe ọ, Oluwa.
2. Oluwa, gbohùn mi, jẹ ki eti rẹ ki o tẹ́ silẹ si ohùn ẹ̀bẹ mi.
3. Oluwa, ibaṣepe iwọ a mã sami ẹ̀ṣẹ, Oluwa, tani iba duro?
4. Nitori idariji wà lọdọ rẹ, ki a le ma bẹ̀ru rẹ.
5. Emi duro dè Oluwa, ọkàn mi duro, ati ninu ọ̀rọ rẹ̀ li emi nṣe ireti.