1. BIKOṢEPE Oluwa ba kọ́ ile na, awọn ti nkọ́ ọ nṣiṣẹ lasan: bikoṣepe Oluwa ba pa ilu mọ́, oluṣọ ji lasan.
2. Asan ni fun ẹnyin ti ẹ dide ni kutukutu lati pẹ iṣiwọ, lati jẹ onjẹ lãlã: bẹ̃li o nfi ire fun olufẹ rẹ̀ loju orun.
3. Kiyesi i, awọn ọmọ ni ini Oluwa: ọmọ inu si li ère rẹ̀.
4. Bi ọfà ti ri li ọwọ alagbara, bẹ̃li awọn ọmọ igbà èwe rẹ.