59. Emi rò ọ̀na mi, mo si yi ẹsẹ mi pada si ẹri rẹ.
60. Emi yara, emi kò si lọra lati pa ofin rẹ mọ́.
61. Okùn awọn enia buburu ti yi mi ka: ṣugbọn emi kò gbagbe ofin rẹ.
62. Lãrin ọganjọ emi o dide lati dupẹ fun ọ nitori ododo idajọ rẹ.
63. Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bẹ̀ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ́ rẹ mọ́.
64. Oluwa, aiye kún fun ãnu rẹ: kọ́ mi ni ilana rẹ.
65. Iwọ ti nṣe rere fun iranṣẹ rẹ Oluwa, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
66. Kọ́ mi ni ìwa ati ìmọ̀ rere; nitori ti mo gbà aṣẹ rẹ gbọ́.