O. Daf 119:57-65 Yorùbá Bibeli (YCE)

57. Oluwa, iwọ ni ipin mi: emi ti wipe, emi o pa ọ̀rọ rẹ mọ́.

58. Emi ti mbẹ̀bẹ oju-rere rẹ tinutinu mi gbogbo: ṣãnu fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

59. Emi rò ọ̀na mi, mo si yi ẹsẹ mi pada si ẹri rẹ.

60. Emi yara, emi kò si lọra lati pa ofin rẹ mọ́.

61. Okùn awọn enia buburu ti yi mi ka: ṣugbọn emi kò gbagbe ofin rẹ.

62. Lãrin ọganjọ emi o dide lati dupẹ fun ọ nitori ododo idajọ rẹ.

63. Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bẹ̀ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ́ rẹ mọ́.

64. Oluwa, aiye kún fun ãnu rẹ: kọ́ mi ni ilana rẹ.

65. Iwọ ti nṣe rere fun iranṣẹ rẹ Oluwa, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

O. Daf 119