O. Daf 119:4-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi.

5. Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́!

6. Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo.

7. Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ.

8. Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata.

O. Daf 119