O. Daf 119:146-154 Yorùbá Bibeli (YCE)

146. Emi kigbe si ọ; gbà mi là, emi o si ma pa ẹri rẹ mọ́.

147. Emi ṣaju kutukutu owurọ, emi ke: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ.

148. Oju mi ṣaju iṣọ-oru, ki emi ki o le ma ṣe iṣaro ninu ọ̀rọ rẹ.

149. Gbohùn mi gẹgẹ bi ãnu rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ.

150. Awọn ti nlepa ìwa-ika sunmọ itosi: nwọn jina si ofin rẹ.

151. Oluwa, iwọ wà ni itosi: otitọ si ni gbogbo aṣẹ rẹ.

152. Lati inu ẹri rẹ, emi ti mọ̀ nigba atijọ pe, iwọ ti fi idi wọn mulẹ lailai.

153. Wò ipọnju mi, ki o si gbà mi: nitori ti emi kò gbagbe ofin rẹ.

154. Gbà ẹjọ mi rò, ki o rà mi pada: sọ mi di ãye nipa ọ̀rọ rẹ.

O. Daf 119