139. Itara mi ti pa mi run nitori ti awọn ọta mi ti gbagbe ọ̀rọ rẹ.
140. Funfun gbò li ọ̀rọ rẹ: nitorina ni iranṣẹ rẹ ṣe fẹ ẹ.
141. Emi kere ati ẹni ẹ̀gan ni: ṣugbọn emi kò gbagbe ẹkọ́ rẹ.
142. Ododo rẹ ododo lailai ni, otitọ si li ofin rẹ.
143. Iyọnu ati àrokan dì mi mu: ṣugbọn aṣẹ rẹ ni inu-didùn mi.
144. Ododo ẹri rẹ aiye-raiye ni: fun mi li oye, emi o si yè.
145. Tinu-tinu mi gbogbo ni mo fi kigbe; Oluwa, da mi lohùn; emi o pa ilana rẹ mọ́.
146. Emi kigbe si ọ; gbà mi là, emi o si ma pa ẹri rẹ mọ́.
147. Emi ṣaju kutukutu owurọ, emi ke: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ.
148. Oju mi ṣaju iṣọ-oru, ki emi ki o le ma ṣe iṣaro ninu ọ̀rọ rẹ.
149. Gbohùn mi gẹgẹ bi ãnu rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ.