O. Daf 119:138-141 Yorùbá Bibeli (YCE)

138. Iwọ paṣẹ ẹri rẹ li ododo ati otitọ gidigidi.

139. Itara mi ti pa mi run nitori ti awọn ọta mi ti gbagbe ọ̀rọ rẹ.

140. Funfun gbò li ọ̀rọ rẹ: nitorina ni iranṣẹ rẹ ṣe fẹ ẹ.

141. Emi kere ati ẹni ẹ̀gan ni: ṣugbọn emi kò gbagbe ẹkọ́ rẹ.

O. Daf 119