O. Daf 119:126-129 Yorùbá Bibeli (YCE)

126. Oluwa, o to akokò fun ọ lati ṣiṣẹ: nitori ti nwọn ti sọ ofin rẹ di ofo.

127. Nitorina emi fẹ aṣẹ rẹ jù wura, ani, jù wura didara lọ.

128. Nitorina emi kà gbogbo ẹkọ́ rẹ si otitọ patapata: emi si korira gbogbo ọ̀na eke.

129. Iyanu li ẹri rẹ: nitorina li ọkàn mi ṣe pa wọn mọ́.

O. Daf 119