O. Daf 119:123-129 Yorùbá Bibeli (YCE)

123. Oju kún mi nitori igbala rẹ, ati nitori ọ̀rọ ododo rẹ.

124. Ṣe si iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi ãnu rẹ, ki o si kọ́ mi ni ilana rẹ.

125. Iranṣẹ rẹ li emi: fun mi li oye, emi o si mọ̀ ẹri rẹ.

126. Oluwa, o to akokò fun ọ lati ṣiṣẹ: nitori ti nwọn ti sọ ofin rẹ di ofo.

127. Nitorina emi fẹ aṣẹ rẹ jù wura, ani, jù wura didara lọ.

128. Nitorina emi kà gbogbo ẹkọ́ rẹ si otitọ patapata: emi si korira gbogbo ọ̀na eke.

129. Iyanu li ẹri rẹ: nitorina li ọkàn mi ṣe pa wọn mọ́.

O. Daf 119