O. Daf 119:104-117 Yorùbá Bibeli (YCE)

104. Nipa ẹkọ́ rẹ emi ni iyè ninu: nitorina mo korira ọ̀na eke gbogbo.

105. Ọ̀rọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ̀ mi, ati imọlẹ si ipa ọ̀na mi.

106. Emi ti bura, emi o si mu u ṣẹ, pe, emi o pa idajọ ododo rẹ mọ́.

107. A pọ́n mi loju gidigidi: Oluwa sọ mi di ãye, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

108. Emi bẹ̀ ọ, Oluwa, gbà ọrẹ atinuwa ẹnu mi, ki o si kọ́ mi ni idajọ rẹ.

109. Ọkàn mi wà li ọwọ mi nigbagbogbo: emi kò si gbagbe ofin rẹ.

110. Awọn enia buburu ti dẹkun silẹ fun mi: ṣugbọn emi kò ṣina kuro nipa ẹkọ́ rẹ.

111. Ẹri rẹ ni ogún mi lailai: nitori awọn li ayọ̀ inu mi.

112. Emi ti fà aiya mi si ati pa ilana rẹ mọ́ nigbagbogbo, ani de opin.

113. Emi korira oniye meji: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ.

114. Iwọ ni ibi ipamọ́ mi ati asà mi: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ.

115. Kuro lọdọ mi, ẹnyin oluṣe-buburu: emi o si pa ofin Ọlọrun mi mọ́.

116. Gbé mi soke gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, ki emi ki o le yè: ki o má si jẹ ki oju ireti mi ki o tì mi.

117. Gbé mi soke, emi o si wà li ailewu: emi o si juba ìlana rẹ nigbagbogbo.

O. Daf 119