9. Israeli, iwọ gbẹkẹle Oluwa: on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.
10. Ara-ile Aaroni, gbẹkẹle Oluwa, on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.
11. Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, gbẹkẹle Oluwa: on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.
12. Oluwa ti nṣe iranti wa: yio bùsi i fun wa: yio bùsi i fun ara-ile Israeli; yio bùsi i fun ara-ile Aaroni.
13. Yio bùsi i fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ati ewe ati àgba.
14. Oluwa yio mu nyin bisi i siwaju ati siwaju, ẹnyin ati awọn ọmọ nyin.
15. Ẹnyin li ẹni-ibukún Oluwa, ti o da ọrun on aiye.
16. Ọrun ani ọrun ni ti Oluwa; ṣugbọn aiye li o fi fun awọn ọmọ enia.
17. Okú kò yìn Oluwa, ati gbogbo awọn ti o sọkalẹ lọ sinu idakẹ.
18. Ṣugbọn awa o ma fi ibukún fun Oluwa, lati igba yi lọ ati si i lailai. Ẹ yìn Oluwa.