1. KÌ iṣe fun wa, Oluwa, kì iṣe fun wa, bikoṣe orukọ rẹ li a fi ogo fun nitori ãnu rẹ, ati nitori otitọ rẹ.
2. Nitori kili awọn keferi yio ṣe wipe, Nibo li Ọlọrun wọn wà nisisiyi?
3. Ṣugbọn Ọlọrun wa mbẹ li ọrun: o nṣe ohun-kohun ti o wù u.
4. Fadaka ati wura li ere wọn, iṣẹ ọwọ enia.
5. Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ: nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò riran.
6. Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò gbọran: nwọn ni imu, ṣugbọn nwọn kò gbõrun.
7. Nwọn li ọwọ, ṣugbọn nwọn kò lò o: nwọn li ẹsẹ, ṣugbọn nwọn kò rìn: bẹ̃ni nwọn kò sọ̀rọ lati ọfun wọn jade.
8. Awọn ti nṣe wọn dabi wọn; bẹ̃li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn.