O. Daf 107:8-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia!

9. Nitori ti o tẹ́ ifẹ ọkàn lọrun, o si fi ire kún ọkàn ti ebi npa.

10. Iru awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ti a dè ninu ipọnju ati ni irin;

11. Nitori ti nwọn ṣọ̀tẹ si ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn si gàn imọ Ọga-ogo:

O. Daf 107