O. Daf 107:40-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

40. O dà ẹ̀gan lù awọn ọmọ-alade, o si mu wọn rìn kiri ni ijù, nibiti ọ̀na kò si.

41. Sibẹ o gbé talaka leke kuro ninu ipọnju, o si ṣe idile wọnni bi agbo-ẹran.

42. Awọn ẹni diduro-ṣinṣin yio ri i, nwọn o si yọ̀: gbogbo ẹ̀ṣẹ ni yio si pa ẹnu rẹ̀ mọ.

43. Ẹniti o gbọ́n, yio si kiyesi nkan wọnyi; awọn na li oye iṣeun-ifẹ Oluwa yio ma ye.

O. Daf 107