O. Daf 107:36-39 Yorùbá Bibeli (YCE)

36. Nibẹ li o si mu awọn ti ebi npa joko, ki nwọn ki o le tẹ ilu do, lati ma gbe.

37. Lati fún irugbin si oko, ki nwọn si gbìn àgbala ajara, ti yio ma so eso ọ̀pọlọpọ.

38. O busi i fun wọn pẹlu, bẹ̃ni nwọn si pọ̀ si i gidigidi; kò si jẹ ki ẹran-ọ̀sin wọn ki o fà sẹhin.

39. Ẹ̀wẹ, nwọn bùku, nwọn si fà sẹhin, nipa inira, ipọnju, ati ikãnu.

O. Daf 107