O. Daf 106:9-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. O ba Okun pupa wi pẹlu, o si gbẹ: bẹ̃li o sìn wọn là ibu ja bi aginju.

10. O si gbà wọn là li ọwọ ẹniti o korira wọn, o si rà wọn pada li ọwọ ọta nì.

11. Omi si bò awọn ọta wọn: ẹnikan wọn kò si kù.

12. Nigbana ni nwọn gbà ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́: nwọn si kọrin iyìn rẹ̀.

13. Nwọn kò pẹ igbagbe iṣẹ rẹ̀: nwọn kò si duro de imọ̀ rẹ̀.

14. Nwọn si ṣe ifẹkufẹ li aginju, nwọn si dan Ọlọrun wò ninu aṣálẹ̀.

15. O si fi ifẹ wọn fun wọn; ṣugbọn o rán rirù si ọkàn wọn.

16. Nwọn ṣe ilara Mose pẹlu ni ibudo, ati Aaroni, ẹni-mimọ́ Oluwa.

17. Ilẹ là, o si gbé Datani mì, o si bò ẹgbẹ́ Abiramu mọlẹ.

18. Iná si ràn li ẹgbẹ́ wọn; ọwọ́ iná na jó awọn enia buburu.

O. Daf 106