O. Daf 106:46-48 Yorùbá Bibeli (YCE)

46. O si mu wọn ri ãnu loju gbogbo awọn ti o kó wọn ni igbekun.

47. Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa, ki o si ṣa wa jọ kuro lãrin awọn keferi, lati ma fi ọpẹ fun orukọ mimọ́ rẹ, ati lati ma ṣogo ninu iyìn rẹ.

48. Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lati aiyeraiye: ki gbogbo enia ki o si ma wipe, Amin. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

O. Daf 106