39. Nwọn si fi iṣẹ ara wọn sọ ara wọn di alaimọ́, nwọn si ṣe panṣaga lọ pẹlu iṣẹ wọn.
40. Nitorina ni ibinu Oluwa ṣe ràn si awọn enia rẹ̀, o si korira awọn enia ini rẹ̀.
41. O si fi wọn le awọn keferi lọwọ; awọn ti o korira wọn si ṣe olori wọn.
42. Awọn ọta wọn si ni wọn lara, nwọn si mu wọn sìn labẹ ọwọ wọn.
43. Igba pupọ li o gbà wọn; sibẹ nwọn fi ìmọ wọn mu u binu, a si rẹ̀ wọn silẹ nitori ẹ̀ṣẹ wọn.
44. Ṣugbọn ninu ipọnju o kiyesi wọn, nigbati o gbọ́ ẹkún wọn.
45. O si ranti majẹmu rẹ̀ fun wọn, o si yi ọkàn pada gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀.
46. O si mu wọn ri ãnu loju gbogbo awọn ti o kó wọn ni igbekun.
47. Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa, ki o si ṣa wa jọ kuro lãrin awọn keferi, lati ma fi ọpẹ fun orukọ mimọ́ rẹ, ati lati ma ṣogo ninu iyìn rẹ.
48. Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lati aiyeraiye: ki gbogbo enia ki o si ma wipe, Amin. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.