26. Nitorina li o ṣe gbé ọwọ rẹ̀ soke si wọn, lati bì wọn ṣubu li aginju:
27. Lati bì iru-ọmọ wọn ṣubu pẹlu lãrin awọn orilẹ-ède, ati lati fún wọn ka kiri ni ilẹ wọnni.
28. Nwọn da ara wọn pọ̀ pẹlu mọ Baali-Peoru, nwọn si njẹ ẹbọ okú.
29. Bayi ni nwọn fi iṣẹ wọn mu u binu: àrun nla si fó si arin wọn.
30. Nigbana ni Finehasi dide duro, o si ṣe idajọ: bẹ̃li àrun nla na si dá.
31. A si kà eyi na si fun u li ododo lati irandiran titi lai.
32. Nwọn bi i ninu pẹlu nibi omi Ijà, bẹ̃li o buru fun Mose nitori wọn:
33. Nitori ti nwọn mu ẹmi rẹ̀ binu, bẹ̃li o fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ̀rọ aiyẹ.
34. Nwọn kò run awọn orilẹ-ède na, niti ẹniti Oluwa paṣẹ fun wọn:
35. Ṣugbọn nwọn da ara wọn pọ̀ mọ́ awọn keferi, nwọn si kọ́ iṣẹ wọn.
36. Nwọn si sìn ere wọn: ti o di ikẹkun fun wọn.
37. Nitõtọ nwọn fi ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn rubọ si oriṣa.