O. Daf 104:8-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Awọn òke nla nru soke; awọn afonifoji nsọkalẹ si ibi ti iwọ ti fi lelẹ fun wọn.

9. Iwọ ti pa àla kan ki nwọn ki o má le kọja rẹ̀; ki nwọn ki o má tun pada lati bò aiye mọlẹ.

10. Iwọ ran orisun si afonifoji, ti nṣàn larin awọn òke.

11. Awọn ni nfi omi mimu fun gbogbo ẹranko igbẹ: awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ npa ongbẹ wọn;

12. Lẹba wọn li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio ni ile wọn, ti nkọrin lãrin ẹka igi.

13. O mbomi rin awọn òke lati iyẹwu rẹ̀ wá: ère iṣẹ ọwọ rẹ tẹ́ aiye lọrun.

O. Daf 104