O. Daf 104:26-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Nibẹ li ọkọ̀ nrìn: nibẹ ni lefiatani nì wà, ti iwọ da lati ma ṣe ariya ninu rẹ̀.

27. Gbogbo wọnyi li o duro tì ọ; ki iwọ ki o le ma fun wọn li onjẹ wọn li akokò wọn.

28. Eyi ti iwọ fi fun wọn ni nwọn nkó: iwọ ṣí ọwọ rẹ, a si fi ohun rere tẹ́ wọn lọrùn.

29. Iwọ pa oju rẹ mọ́, ara kò rọ̀ wọn: iwọ gbà ẹmi wọn, nwọn kú, nwọn si pada si erupẹ wọn.

30. Iwọ rán ẹmi rẹ jade, a si da wọn: iwọ si sọ oju ilẹ di ọtun.

31. Ogo Oluwa yio wà lailai: Oluwa yio yọ̀ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀.

32. O bojuwo aiye, o si warìrì: o fi ọwọ kàn òke, nwọn si ru ẹ̃fin.

33. Emi o ma kọrin si Oluwa nigbati mo wà lãye: emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun mi ni igba aiye mi.

34. Jẹ ki iṣaro mi ki o mu inu rẹ̀ dùn: emi o mã yọ̀ ninu Oluwa.

35. Jẹ ki awọn ẹlẹṣẹ ki o run kuro li aiye, ki awọn enia buburu ki o má si mọ. Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

O. Daf 104