O. Daf 102:21-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Lati sọ orukọ Oluwa ni Sioni, ati iyìn rẹ̀ ni Jerusalemu.

22. Nigbati a kó awọn enia jọ pọ̀ ati awọn ijọba, lati ma sìn Oluwa.

23. O rẹ̀ agbara mi silẹ li ọ̀na; o mu ọjọ mi kuru.

24. Emi si wipe, Ọlọrun mi, máṣe mu mi kuro li agbedemeji ọjọ mi: lati irandiran li ọdun rẹ.

O. Daf 102