O. Daf 102:17-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Yio juba adura awọn alaini, kì yio si gàn adura wọn.

18. Eyi li a o kọ fun iran ti mbọ̀; ati awọn enia ti a o da yio ma yìn Oluwa.

19. Nitori ti o wò ilẹ lati òke ibi-mimọ́ rẹ̀ wá; lati ọrun wá ni Oluwa bojuwo aiye;

20. Lati gbọ́ irora ara-tubu; lati tú awọn ti a yàn si ikú silẹ;

O. Daf 102