9. O lùmọ ni ibi ìkọkọ bi kiniun ninu pantiri: o lùmọ lati mu talaka: a si mu talaka, nigbati o ba fà a sinu àwọn rẹ̀.
10. O ba, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, ki talaka ki o le bọ́ si ọwọ agbara rẹ̀.
11. O ti wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun ti gbagbe: o pa oju rẹ̀ mọ́; on kì yio ri i lailai.
12. Dide, Oluwa; Ọlọrun, gbé ọwọ rẹ soke: máṣe gbagbe olupọnju.
13. Ẽṣe ti enia buburu fi ngàn Ọlọrun? o wi li ọkàn rẹ̀ pe, Iwọ kì yio bère.