Num 8:21-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Awọn ọmọ Lefi si wẹ̀ ara wọn mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn; Aaroni si mú wọn wá li ọrẹ fifì siwaju OLUWA: Aaroni si ṣètutu fun wọn lati wẹ̀ wọn mọ́.

22. Lẹhin eyinì ni awọn ọmọ Lefi si wọle lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ niwaju Aaroni, ati niwaju awọn ọmọ rẹ̀: bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose niti awọn ọmọ Lefi, bẹ̃ni nwọn ṣe si wọn.

23. OLUWA si sọ fun Mose pe,

24. Eyi ni ti awọn ọmọ Lefi: lati ẹni ọdún mẹdọgbọ̀n lọ ati jù bẹ̃ lọ ni ki nwọn ki o ma wọle lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ.

25. Ati lati ẹni ãdọta ọdún ni ki nwọn ki o ṣiwọ iṣẹ-ìsin, ki nwọn ki o má si ṣe sìn mọ́;

Num 8