Num 4:18-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ẹ máṣe ke ẹ̀ya idile awọn ọmọ Kohati kuro lãrin awọn ọmọ Lefi:

19. Ṣugbọn bayi ni ki ẹ ṣe fun wọn, ki nwọn ki o le yè, ki nwọn ki o má ba kú, nigbati nwọn ba sunmọ ohun mimọ́ julọ: ki Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wọnú ilé, ki nwọn si yàn wọn olukuluku si iṣẹ rẹ̀ ati si ẹrù rẹ̀;

20. Ṣugbọn nwọn kò gbọdọ wọle lọ lati wò ohun mimọ́ ni iṣẹju kan, ki nwọn ki o má ba kú.

21. OLUWA si sọ fun Mose pe,

22. Kà iye awọn ọmọ Gerṣoni pẹlu, gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn;

23. Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki o kaye wọn; gbogbo awọn ti o wọnu-ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ.

24. Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni, lati sìn ati lati rù ẹrù:

25. Awọn ni yio si ma rù aṣọ-ikele agọ́, ati agọ́ ajọ, ibori rẹ̀, ati ibori awọ seali ti mbẹ lori rẹ̀, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ;

26. Ati aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agbalá, ti mbẹ lẹba agọ́ ati lẹba pẹpẹ yiká, ati okùn wọn, ati gbogbo ohun-èlo iṣẹ-ìsin wọn, ati ohun gbogbo ti a ṣe fun wọn; bẹ̃ni nwọn o ma sìn.

27. Nipa aṣẹ Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ki gbogbo iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Gerṣoni jẹ́, ni gbogbo ẹrù wọn, ati ni gbogbo iṣẹ-ìsin wọn: ki ẹnyin si yàn wọn si itọju gbogbo ẹrù wọn.

28. Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni ninu agọ́ ajọ: ki itọju wọn ki o si wà li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa.

29. Ati awọn ọmọ Merari, ki iwọ ki o kà wọn gẹgẹ bi idile wọn, nipa ile baba wọn;

30. Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki iwọ ki o kà wọn, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ́.

31. Eyi si ni itọju ẹrù wọn, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ-ìsin wọn ninu agọ́ ajo; awọn apáko agọ́, ati ọpá-idabu rẹ̀, ati opó rẹ̀, ati ìhò-ìtẹbọ rẹ̀,

32. Ati opó agbalá yiká, ati ihò-ìtẹbọ wọn, ati ẽkàn wọn, ati okùn wọn, pẹlu ohun-èlo wọn gbogbo, ati pẹlu ohun-ìsin wọn gbogbo: li orukọ li orukọ ni ki ẹnyin ki o kà ohun-èlo ti iṣe itọju ẹrù wọn.

33. Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn gbogbo, ninu agọ́ ajọ, labẹ Itamari ọmọ Aaroni alufa.

Num 4