6. Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ nipa ti awọn ọmọbinrin Selofehadi, wipe, Ki nwọn ki o ṣe aya ẹniti o wù wọn; kiki pe, ninu idile ẹ̀ya baba wọn ni ki nwọn ki o gbeyawo si.
7. Bẹ̃ni ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli ki yio yi lati ẹ̀ya de ẹ̀ya: nitori ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o le faramọ́ ilẹ-iní ẹ̀ya awọn baba rẹ̀:
8. Ati gbogbo awọn ọmọbinrin, ti o ní ilẹ-iní ninu ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli, ki o ṣe aya fun ọkan ninu idile ẹ̀ya baba rẹ̀, ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o le ma jogún ilẹ-iní awọn baba rẹ̀.
9. Bẹ̃ni ki ilẹ-iní ki o máṣe yi lati ẹ̀ya kan lọ si ẹ̀ya keji; ṣugbọn ki olukuluku ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli ki o faramọ́ ilẹ-iní tirẹ̀.
10. Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọbinrin Selofehadi ṣe:
11. Nitoripe a gbé Mala, Tirsa, ati Hogla, ati Milka, ati Noa, awọn ọmọbinrin Selofehadi niyawo fun awọn ọmọ arakunrin baba wọn.
12. A si gbé wọn niyawo sinu idile awọn ọmọ Manasse ọmọ Josefu, ilẹ-ini wọn si duro ninu ẹ̀ya idile baba wọn.
13. Wọnyi ni aṣẹ ati idajọ ti OLUWA palaṣẹ fun awọn ọmọ Israeli lati ọwọ́ Mose, ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko.