Ati nigbati ọdún jubeli awọn ọmọ Israeli ba dé, nigbana li a o fi ilẹ-iní wọn kún ilẹ-iní ẹ̀ya ti a gbé wọn si: bẹ̃li a o si gbà ilẹ-iní wọn kuro ninu ilẹ-iní ẹ̀ya awọn baba wa.