48. Nwọn si ṣí kuro ni òke Abarimu, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko.
49. Nwọn si dó si ẹba Jordani, lati Beti-jeṣimotu titi dé Abeli-ṣittimu ni pẹtẹlẹ̀ Moabu.
50. OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe,
51. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke odò Jordani si ilẹ Kenaani:
52. Nigbana ni ki ẹnyin ki o lé gbogbo awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; ki ẹnyin si run gbogbo aworán wọn, ki ẹnyin si run gbogbo ere didà wọn, ki ẹnyin si wó gbogbo ibi giga wọn palẹ:
53. Ki ẹnyin ki o si gbà ilẹ na, ki ẹnyin ki o si ma gbé inu rẹ̀: nitoripe mo ti fi ilẹ na fun nyin lati ní i.