37. Nwọn si ṣí kuro ni Kadeṣi, nwọn si dó si òke Hori, leti ilẹ Edomu.
38. Aaroni alufa si gùn òke Hori lọ nipa aṣẹ OLUWA, o si kú nibẹ̀, li ogoji ọdún lẹhin ti awọn ọmọ Israeli ti ilẹ Egipti jade wá, li ọjọ́ kini oṣù karun.
39. Aaroni si jẹ́ ẹni ọgọfa ọdún o le mẹta nigbati o kú li òke Hori.
40. Ara Kenaani, ọba Aradi, ti ngbé ìha gusù ni ilẹ Kenaani, o gburó pe awọn ọmọ Israeli mbọ̀.
41. Nwọn si ṣí kuro ni òke Hori, nwọn si dó si Salmona.
42. Nwọn si ṣí ni Salmona, nwọn si dó si Punoni.