1. MOSE si sọ fun awọn olori awọn ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli, wipe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ.
2. Bi ọkunrin kan ba jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, tabi ti o ba bura lati fi dè ara rẹ̀ ni ìde, ki on ki o máṣe bà ọ̀rọ rẹ̀ jẹ; ki on ki o ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ti ẹnu rẹ̀ jade.
3. Bi obinrin kan pẹlu ba si jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, ti o si dè ara rẹ̀ ni ìde, ni ile baba rẹ̀ ni ìgba ewe rẹ̀;
4. Ti baba rẹ̀ si gbọ́ ẹjẹ́ rẹ̀, ati ìde rẹ̀ ti o fi dè ara rẹ̀, ti baba rẹ̀ ba si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i; njẹ ki gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ ki o duro, ati gbogbo ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro.
5. Ṣugbọn bi baba rẹ̀ ba kọ̀ fun u li ọjọ́ na ti o gbọ́; kò sí ọkan ninu ẹjẹ́ rẹ̀, tabi ninu ìde ti o fi dè ara rẹ̀, ti yio duro: OLUWA yio si darijì i, nitoriti baba rẹ̀ kọ̀ fun u.
6. Bi o ba si kúku li ọkọ, nigbati o jẹ́ ẹjẹ́, tabi ti o sọ̀rọ kan lati ẹnu rẹ̀ jade, ninu eyiti o fi dè ara rẹ̀ ni ìde;
7. Ti ọkọ rẹ̀ si gbọ́, ti o si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ ẹjẹ́ rẹ̀ yio duro, ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro.
8. Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kọ̀ fun u li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ on o mu ẹjẹ́ rẹ̀ ti o jẹ́ ati ohun ti o ti ẹnu rẹ̀ jade, eyiti o fi dè ara rẹ̀ dasan: OLUWA yio si darijì i.
9. Ṣugbọn gbogbo ẹjẹ́ opó, ati ti obinrin ti a kọ̀silẹ, ti nwọn fi dè ara wọn, yio wà lọrùn rẹ̀.
10. Bi o ba si jẹjẹ́ ni ile ọkọ rẹ̀, tabi ti o si fi ibura dè ara rẹ̀ ni ìde,
11. Ti ọkọ rẹ̀ si gbọ́, ti o si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i, ti kò si kọ̀ fun u: njẹ gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ ni yio duro, ati gbogbo ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro.
12. Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba sọ wọn dasan patapata li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ ohunkohun ti o ti ẹnu rẹ̀ jade nipasẹ̀ ẹjẹ́ rẹ̀, tabi nipasẹ̀ ìde ọkàn rẹ̀, ki yio duro: ọkọ rẹ̀ ti sọ wọn dasan; OLUWA yio si darijì i.
13. Gbogbo ẹjẹ́ ati ibura ìde lati fi pọ́n ara loju, ọkọ rẹ̀ li o le mu u duro, o si le sọ ọ dasan.