19. Ati awọn ọmọ Kohati gẹgẹ bi idile wọn: Amramu, ati Ishari, Hebroni, ati Usieli.
20. Ati awọn ọmọ Merari gẹgẹ bi idile wọn; Mali, ati Muṣi. Wọnyi ni awọn idile Lefi gẹgẹ bi ile baba wọn.
21. Ti Gerṣoni ni idile awọn ọmọ Libni, ati idile awọn ọmọ Ṣimei; wọnyi ni idile awọn ọmọ Gerṣoni.
22. Awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin, lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani iye awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgbata o le ẹdẹgbẹjọ.
23. Awọn idile awọn ọmọ Gerṣoni ni ki o dó lẹhin agọ́ ni ìha ìwọ-õrùn.
24. Ati Eliasafu ọmọ Laeli ni ki o ṣe olori ile baba awọn ọmọ Gerṣoni.
25. Ati itọju awọn ọmọ Gerṣoni ninu agọ́ ajọ ni, Agọ́, ibori rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ ti ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ,
26. Ati aṣọ isorọ̀ ti agbalá, ati aṣọtita ti ẹnu-ọ̀na agbalá, ti mbẹ lẹba agọ́, ati lẹba pẹpẹ yiká, ati okùn rẹ̀ fun gbogbo iṣẹ-ìsin rẹ̀.
27. Ati ti Kohati ni idile awọn ọmọ Amramu, ati idile ti awọn ọmọ Ishari, ati idile ti awọn ọmọ Hebroni, ati idile ti awọn ọmọ Usieli: wọnyi ni idile awọn ọmọ Kohati.
28. Gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ẹgba mẹrin o le ẹgbẹta, ti nṣe itọju ibi-mimọ́.
29. Awọn idile ti awọn ọmọ Kohati ni ki o pagọ́ lẹba agọ́ si ìha gusù.
30. Ati Elisafani ọmọ Usieli ni ki o ṣe olori ile baba awọn idile awọn ọmọ Kohati.
31. Apoti, ati tabeli, ati ọpá-fitila, ati pẹpẹ wọnni, ati ohun-èlo ibi-mimọ́, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ alufa, ati aṣọ-tita, ati gbogbo ohun-èlo iṣẹ-ìsin rẹ̀, ni yio jẹ́ ohun itọju wọn.
32. Eleasari ọmọ Aaroni alufa ni yio si ṣe olori awọn olori awọn ọmọ Lefi, on ni yio si ma ṣe itọju awọn ti nṣe itọju ibi-mimọ́.
33. Ti Merari ni idile awọn ọmọ Mali, ati idile awọn ọmọ Musi: wọnyi ni idile Merari.