Num 3:11-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. OLUWA si sọ fun Mose pe,

12. Ati emi, kiyesi i, emi ti gbà awọn ọmọ Lefi kuro lãrin awọn ọmọ Israeli ni ipò gbogbo akọ́bi ti o ṣí inu ninu awọn ọmọ Israeli; nitorina ti emi li awọn ọmọ Lefi iṣe:

13. Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi; nitoripe li ọjọ́ na ti mo kọlù gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ni mo yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun ara mi ni Israeli, ati enia ati ẹran: ti emi ni nwọn o ma ṣe: Emi li OLUWA.

14. OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai pe,

15. Kaye awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn: gbogbo ọkunrin lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ni ki iwọ ki o kà wọn.

16. Mose si kà wọn gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, bi a ti paṣẹ fun u.

17. Wọnyi si ni awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi orukọ wọn; Gerṣoni, ati Kohati, ati Merari.

18. Wọnyi si ni orukọ awọn ọmọ Gerṣoni gẹgẹ bi idile wọn; Libni ati Ṣimei.

19. Ati awọn ọmọ Kohati gẹgẹ bi idile wọn: Amramu, ati Ishari, Hebroni, ati Usieli.

20. Ati awọn ọmọ Merari gẹgẹ bi idile wọn; Mali, ati Muṣi. Wọnyi ni awọn idile Lefi gẹgẹ bi ile baba wọn.

21. Ti Gerṣoni ni idile awọn ọmọ Libni, ati idile awọn ọmọ Ṣimei; wọnyi ni idile awọn ọmọ Gerṣoni.

22. Awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin, lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani iye awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgbata o le ẹdẹgbẹjọ.

23. Awọn idile awọn ọmọ Gerṣoni ni ki o dó lẹhin agọ́ ni ìha ìwọ-õrùn.

24. Ati Eliasafu ọmọ Laeli ni ki o ṣe olori ile baba awọn ọmọ Gerṣoni.

25. Ati itọju awọn ọmọ Gerṣoni ninu agọ́ ajọ ni, Agọ́, ibori rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ ti ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ,

Num 3