7. Ki ẹnyin ki o si ní apejọ mimọ́ ni ijọ́ kẹwa oṣù keje na yi; ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan:
8. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun si OLUWA fun õrùn didùn; ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan; ki nwọn ki o si jẹ́ alailabùku fun nyin:
9. Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji ọsuwọn fun àgbo kan,
10. Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje:
11. Obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ètutu, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn.
12. Ati ni ijọ́ kẹdogun oṣù keje, ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan, ki ẹnyin ki o si ṣe ajọ fun OLUWA ni ijọ́ meje:
13. Ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ sisun kan, ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu mẹtala, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan; ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku:
14. Ati ẹbọ ohun-jijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, bẹ̃ni fun akọmalu mẹtẹtala, idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan, bẹ̃ni fun àgbo mejeji,
15. Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mẹrẹrinla: