Num 29:5-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, lati ṣètutu fun nyin;

6. Pẹlu ẹbọ sisun oṣù, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn, gẹgẹ bi ìlana wọn, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.

7. Ki ẹnyin ki o si ní apejọ mimọ́ ni ijọ́ kẹwa oṣù keje na yi; ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan:

8. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun si OLUWA fun õrùn didùn; ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan; ki nwọn ki o si jẹ́ alailabùku fun nyin:

9. Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji ọsuwọn fun àgbo kan,

10. Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje:

11. Obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ètutu, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn.

12. Ati ni ijọ́ kẹdogun oṣù keje, ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan, ki ẹnyin ki o si ṣe ajọ fun OLUWA ni ijọ́ meje:

13. Ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ sisun kan, ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu mẹtala, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan; ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku:

14. Ati ẹbọ ohun-jijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, bẹ̃ni fun akọmalu mẹtẹtala, idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan, bẹ̃ni fun àgbo mejeji,

15. Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mẹrẹrinla:

16. Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.

17. Ati ni ijọ́ keji ni ki ẹnyin ki o fi ẹgbọrọ akọmalu mejila, àgbo meji, ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku rubọ:

Num 29