28. Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
29. Ati ni ijọ́ kẹfa akọmalu mẹjọ, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku:
30. Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:
31. Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
32. Ati ni ijọ́ keje akọmalu meje, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku:
33. Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:
34. Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
35. Ni ijọ́ kẹjọ ki ẹnyin ki o ní ajọ ti o ni ironu: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan.
36. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA: akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku:
37. Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:
38. Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
39. Ẹbọ wọnyi ni ki ẹnyin ki o ru si OLUWA li ajọ nyin, pẹlu ẹjẹ́ nyin, ati ẹbọ ọrẹ-atinuwa nyin, fun ẹbọ sisun nyin, ati fun ẹbọ ohunjijẹ nyin, ati fun ẹbọ ohun mimu nyin, ati fun ẹbọ alafia nyin.
40. Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ fun Mose.