Num 27:18-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. OLUWA si sọ fun Mose pe, Iwọ mú Joṣua ọmọ Nuni, ọkunrin ninu ẹniti ẹmi wà, ki o si fi ọwọ́ rẹ lé e lori;

19. Ki o si mu u duro niwaju Eleasari alufa, ati niwaju gbogbo ijọ; ki o si fi aṣẹ fun u li oju wọn.

20. Ki iwọ ki o si fi ninu ọlá rẹ si i lara, ki gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli ki o le gbà a gbọ́.

21. Ki on si duro niwaju Eleasari alufa, ẹniti yio bère fun u nipa idajọ Urimu niwaju OLUWA: nipa ọ̀rọ rẹ̀ ni ki nwọn ki o jade lọ, ati nipa ọ̀rọ rẹ̀ ni ki nwọn ki o wọle, ati on, ati gbogbo awọn ọmọ Israeli pẹlu rẹ̀, ani gbogbo ijọ.

22. Mose si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun u: o si mú Joṣua, o si mu u duro niwaju Eleasari alufa, ati niwaju gbogbo ijọ:

23. O si fi ọwọ́ rẹ̀ lé e lori, o si fi aṣẹ fun u, bi OLUWA ti wi lati ọwọ́ Mose.

Num 27