Num 27:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni awọn ọmọbinrin Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ti idile Manasse ọmọ Josefu wá: wọnyi si li orukọ awọn ọmọbinrin rẹ̀; Mala, Noa, ati Hogla, ati Milka, ati Tirsa.

2. Nwọn si duro niwaju Mose, ati niwaju Eleasari alufa, ati niwaju awọn olori ati gbogbo ijọ, li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, wipe,

3. Baba wa kú li aginjù, on kò si sí ninu ẹgbẹ awọn ti o kó ara wọn jọ pọ̀ si OLUWA ninu ẹgbẹ Kora: ṣugbọn o kú ninu ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀; kò si lí ọmọkunrin.

4. Ẽhaṣe ti orukọ, baba wa yio fi parẹ kuro ninu idile rẹ̀, nitoriti kò lí ọmọkunrin? Fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin baba wa.

5. Mose si mú ọ̀ran wọn wá siwaju OLUWA.

6. OLUWA si sọ fun Mose pe,

7. Awọn ọmọbinrin Selofehadi sọ rere: nitõtọ, fun wọn ni ilẹ-iní kan lãrin awọn arakunrin baba wọn; ki iwọ ki o si ṣe ki ilẹ-iní baba wọn ki o kọja sọdọ wọn.

8. Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ọkunrin kan ba kú, ti kò si lí ọmọkunrin, njẹ ki ẹnyin ki o ṣe ki ilẹ-iní rẹ̀ ki o kọja sọdọ ọmọbinrin rẹ̀.

Num 27