56. Gẹgẹ bi kèké ni ki a pín ilẹ-iní na lãrin awọn pupọ̀ ati diẹ.
57. Wọnyi si li awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, gẹgẹ bi idile wọn: ti Gerṣoni, idile awọn ọmọ Gerṣoni: ti Kohati, idile awọn ọmọ Kohati: ti Merari, idile awọn ọmọ Merari.
58. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Lefi: idile awọn ọmọ Libni, idile awọn ọmọ Hebroni, idile awọn ọmọ Mali, idile awọn ọmọ Muṣi, idile awọn ọmọ Kora. Kohati si bi Amramu.
59. Orukọ aya Amramu a si ma jẹ́ Jokebedi, ọmọbinrin Lefi, ti iya rẹ̀ bi fun Lefi ni Egipti: on si bi Aaroni, ati Mose, ati Miriamu arabinrin wọn fun Amramu.
60. Ati fun Aaroni li a bi Nadabu ati Abihu, Eleasari ati Itamari.
61. Ati Nadabu ati Abihu kú, nigbati nwọn mú iná ajeji wá siwaju OLUWA.
62. Awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanla o le ẹgbẹrun, gbogbo awọn ọkunrin lati ọmọ oṣù kan ati jù bẹ̃ lọ: nitoripe a kò kà wọn kún awọn ọmọ Israeli, nitoriti a kò fi ilẹ-iní fun wọn ninu awọn ọmọ Israeli.
63. Wọnyi li awọn ti a kà lati ọwọ́ Mose ati Eleasari alufa wá, awọn ẹniti o kà awọn ọmọ Israeli ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko.