14. Njẹ nisisiyi si kiyesi i, emi nlọ sọdọ awọn enia mi: wá, emi o si sọ fun ọ ohun ti awọn enia yi yio ṣe si awọn enia rẹ li ẹhin-ọla.
15. O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ ṣí nwi:
16. Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o si mọ̀ imọ̀ Ọga-Ogo, ti o ri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ si ṣí:
17. Emi ri i, ṣugbọn ki iṣe nisisiyi: emi si wò o, ṣugbọn kò sunmọtosi: irawọ kan yio ti inu Jakobu jade wá, ọpa-alade kan yio si ti inu Israeli dide, yio si kọlù awọn igun Moabu, yio si ṣẹ́ gbogbo awọn ọmọ irọkẹ̀kẹ.