7. Nitorina li awọn enia na ṣe tọ̀ Mose wá, nwọn si wipe, Awa ti ṣẹ̀, nitoriti awa ti bá OLUWA ati iwọ sọ̀; gbadura si OLUWA ki o mú ejò wọnyi kuro lọdọ wa. Mose si gbadura fun awọn enia na.
8. OLUWA si wi fun Mose pe, Rọ ejò amubina kan, ki o si fi i sori ọpá-gigùn kan: yio si ṣe, olukuluku ẹniti ejò ba bùṣan, nigbati o ba wò o, yio yè.
9. Mose si rọ ejò idẹ kan, o si fi i sori ọpá-gigùn na: o si ṣe, pe bi ejò kan ba bù enia kan ṣan, nigbati o ba wò ejò idẹ na, on a yè.
10. Awọn ọmọ Israeli si ṣi siwaju, nwọn si dó ni Obotu.
11. Nwọn si ṣi lati Obotu lọ, nwọn si dó si Iye-abarimu, li aginjù ti mbẹ niwaju Moabu, ni ìha ìla-õrùn.
12. Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si afonifoji Seredi.
13. Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ti mbẹ li aginjù, ti o ti àgbegbe awọn ọmọ Amori wá: nitoripe Arnoni ni ipinlẹ Moabu, lãrin Moabu ati awọn Amori.