26. Nitoripe Heṣboni ni ilunla Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ẹniti o ti bá ọba Moabu atijọ jà, ti o si gbà gbogbo ilẹ rẹ̀ li ọwọ́ rẹ̀, titi dé Arnoni.
27. Nitorina awọn ti nkọrin owe a ma wipe, Wá si Heṣboni, jẹ ki a tẹ̀ ilunla Sihoni dó ki a si tun fi idi rẹ̀ mulẹ:
28. Nitoriti iná kan ti Heṣboni jade lọ, ọwọ́-iná kan lati ilunla Sihoni: o si run Ari ti Moabu, ati awọn oluwa ibi giga Arnoni.
29. Egbé ni fun iwọ, Moabu! Ẹ gbé, ẹnyin enia Kemoṣi: on ti fi awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin bi isansa, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin bi igbekun, fun Sihoni ọba awọn ọmọ Amori.
30. Awa tafà si wọn; Heṣboni ṣegbé titi dé Diboni, awa si ti run wọn titi dé Nofa, ti o dé Medeba.
31. Bẹ̃li awọn ọmọ Israeli joko ni ilẹ awọn ọmọ Amori.