2. Ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o pa agọ́ rẹ̀ lẹba ọpagun rẹ̀, pẹlu asia ile baba wọn: ki nwọn ki o pagọ́ kọjusi agọ́ ajọ yiká.
3. Ki awọn ti iṣe ti ọpagun ibudó Juda ki o dó ni ìha ìla-õrùn si ìha ìla-õrùn, gẹgẹ bi ogun wọn: Naṣoni ọmọ Amminadabu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Juda.
4. Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilogoji o le ẹgbẹta.
5. Ati awọn ti o pagọ́ gbè e ki o jẹ́ ẹ̀ya Issakari: Netaneli ọmọ Suari yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Issakari:
6. Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilọgbọ̀n o le irinwo.
7. Ati ẹ̀ya Sebuluni: Eliabu ọmọ Heloni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Sebuluni:
8. Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mejidilọgbọ̀n o le egbeje.
9. Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Juda jẹ́ ẹgba mẹtalelãdọrun o le irinwo, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn yi ni yio kọ́ ṣí.
10. Ni ìha gusù ni ki ọpagun ibudó Reubeni ki o wà, gẹgẹ bi ogun wọn: Elisuru ọmọ Ṣedeuru yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Reubeni:
11. Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtalelogun o le ẹdẹgbẹta.
12. Ati awọn ti o pagọ́ tì i ki o jẹ́ ẹ̀ya Simeoni: Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai ni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Simeoni:
13. Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkandilọgbòn o le ẹdegbeje.
14. Ati ẹ̀ya Gadi: Eliasafu ọmọ Deueli ni yio si jẹ́ olori ogun ti awọn ọmọ Gadi:
15. Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ãdọtalelẹgbẹjọ.
16. Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Reubeni jẹ́ ẹgba marundilọgọrin o le ãdọtalelegbeje, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn ni yio si ṣí ṣikeji.