16. Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Reubeni jẹ́ ẹgba marundilọgọrin o le ãdọtalelegbeje, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn ni yio si ṣí ṣikeji.
17. Nigbana ni agọ́ ajọ yio si ṣí, pẹlu ibudó, awọn ọmọ Lefi lãrin ibudó: bi nwọn ti dó bẹ̃ni nwọn o ṣí, olukuluku ni ipò rẹ̀, pẹlu ọpagun wọn.
18. Ni ìha ìwọ-õrùn ni ki ọpagun ibudó Efraimu ki o wà gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Efraimu:
19. Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta.