Num 19:13-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn okú ẹnikan ti o kú, ti kò si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, o bà agọ́ OLUWA jẹ́; ọkàn na li a o si ke kuro ninu Israeli: nitoriti a kò wọ́n omi ìyasapakan si i lara, alaimọ́ li o jẹ̀; aimọ́ rẹ̀ mbẹ lara rẹ̀ sibẹ̀,

14. Eyi li ofin na, nigbati enia kan ba kú ninu agọ́ kan: gbogbo ẹniti o wọ̀ inu agọ́ na, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu agọ́ na, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje.

15. Ati ohun-èlo gbogbo ti o ṣi silẹ, ti kò ní ideri lori rẹ̀, alaimọ́ ni.

16. Ẹnikẹni ti o ba si fọwọkàn ẹnikan ti a fi idà pa ni gbangba igbẹ́, tabi okú kan, tabi egungun ẹnikan, tabi isà-okú, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje.

17. Ati fun ẹni aimọ́ kan ki nwọn ki o mú ninu ẽru sisun ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì, ki a si bù omi ti nṣàn si i ninu ohun-èlo kan:

18. Ki ẹnikan ti o mọ́ ki o si mú hissopu, ki o si tẹ̀ ẹ bọ̀ inu omi na, ki o si fi i wọ́n agọ́ na, ati ohun-èlo gbogbo, ati sara awọn enia ti o wá nibẹ̀, ati sara ẹniti o fọwọkàn egungun kan, tabi ẹnikan ti a pa, tabi ẹnikan ti o kú, tabi isà-okú:

19. Ki ẹniti o mọ́ na ki o si bùwọ́n alaimọ́ na ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje: ati ni ijọ́ keje ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́; ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omì, yio si di mimọ́ li aṣalẹ.

20. Ṣugbọn ẹniti o ba jẹ́ alaimọ́, ti kò ba wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ, nitoriti o bà ibi-mimọ́ OLUWA jẹ́: a kò si ta omi ìyasapakan si i lara; alaimọ́ li on.

21. Yio si ma jẹ́ ìlana lailai fun wọn, pe ẹniti o ba bú omi ìyasapakan wọ́n ẹni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀; ati ẹniti o si fọwọkàn omi ìyasapakan na yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

22. Ati ohunkohun ti ẹni aimọ́ na ba si farakàn, yio jẹ́ alaimọ́; ọkàn ti o ba si farakàn a, yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

Num 19