6. Ati emi, kiyesi i, mo ti mú awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Lefi kuro ninu awọn ọmọ Israeli: ẹnyin li a fi wọn fun bi ẹ̀bun fun OLUWA, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ.
7. Iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio si ma ṣe itọju iṣẹ-alufa nyin niti ohun gbogbo ti iṣe ti pẹpẹ, ati ti inu aṣọ-ikele: ẹnyin o si ma sìn: emi ti fi iṣẹ-alufa nyin fun nyin, bi iṣẹ-ìsin ẹ̀bun: alejò ti o ba si sunmọtosi li a o pa.
8. OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Kiyesi i, emi si ti fi itọju ẹbọ igbesọsoke mi fun ọ pẹlu, ani gbogbo ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, iwọ li emi fi wọn fun ni ipín, ati fun awọn ọmọ rẹ, bi ipín lailai.
9. Eyi ni yio ṣe tirẹ ninu ohun mimọ́ julọ, ti a mú kuro ninu iná; gbogbo ọrẹ-ẹbọ wọn, gbogbo ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹbi wọn, ti nwọn o mú fun mi wá, mimọ́ julọ ni yio jasi fun iwọ ati fun awọn ọmọ rẹ.
10. Bi ohun mimọ́ julọ ni ki iwọ ki o ma jẹ ẹ: gbogbo ọkunrin ni yio jẹ ẹ; mimọ́ ni yio jẹ́ fun ọ.
11. Eyi si ni tirẹ; ẹbọ igbesọsoke ẹ̀bun wọn, pẹlu gbogbo ẹbọ fifì awọn ọmọ Israeli: emi ti fi wọn fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: gbogbo awọn ti o mọ́ ninu ile rẹ ni ki o jẹ ẹ.
12. Gbogbo oróro daradara, ati gbogbo ọti-waini daradara, ati alikama, akọ́so ninu wọn ti nwọn o mú fun OLUWA wá, iwọ ni mo fi wọn fun.
13. Akọ́so gbogbo ohun ti o wà ni ilẹ wọn, ti nwọn o mú fun OLUWA wá, tirẹ ni yio jẹ́; gbogbo ẹniti o mọ́ ni ile rẹ ni ki o jẹ ẹ.
14. Ohun ìyasọtọ gbogbo ni Israeli ni ki o jẹ́ tirẹ.
15. Gbogbo akọ́bi ninu gbogbo ohun alãye, ti nwọn o mú wa fun OLUWA, iba ṣe ti enia tabi ti ẹranko, ki o jẹ́ tirẹ: ṣugbọn rirà ni iwọ o rà akọ́bi enia silẹ, ati akọ́bi ẹran alaimọ́ ni ki iwọ ki o rà silẹ.
16. Gbogbo awọn ti a o ràsilẹ, lati ẹni oṣù kan ni ki iwọ ki o ràsilẹ, gẹgẹ bi idiyelé rẹ, li owo ṣekeli marun, nipa ṣekeli ibi-mimọ́ (ti o jẹ́ ogun gera).
17. Ṣugbọn akọ́bi akọmalu, tabi akọbi agutan, tabi akọ́bi ewurẹ, ni iwọ kò gbọdọ ràsilẹ; mimọ́ ni nwọn: ẹ̀jẹ wọn ni ki iwọ ki o ta sori pẹpẹ, ki iwọ ki o si sun ọrá wọn li ẹbọ ti a fi iná ṣe, fun õrùn didùn si OLUWA.
18. Ki ẹran wọn ki o si jẹ́ tirẹ, bi àiya fifì, ati bi itan ọtún, ni yio jẹ́ tirẹ.
19. Gbogbo ẹbọ igbesọsoke ohun mimọ́ wọnni, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun OLUWA, ni mo ti fi fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: majẹmu iyọ̀ ni lailai niwaju OLUWA fun ọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ.
20. OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Iwọ ki yio ní iní ninu ilẹ wọn, bẹ̃ni iwọ ki yio ní ipín lãrin wọn: Emi ni ipín rẹ ati iní rẹ lãrin awọn ọmọ Israeli.