22. Nitori gbogbo awọn enia wọnyi ti o ti ri ogo mi, ati iṣẹ-àmi mi, ti mo ti ṣe ni Egipti ati li aginjù, ti nwọn si dan mi wò nigba mẹwa yi, ti nwọn kò si fetisi ohùn mi;
23. Nitõtọ nwọn ki yio ri ilẹ na ti mo ti fi bura fun awọn baba wọn, bẹ̃ni ọkan ninu awọn ti o gàn mi ki yio ri i:
24. Ṣugbọn Kalebu iranṣẹ mi, nitoriti o ní ọkàn miran ninu rẹ̀, ti o si tẹle mi mọtimọti, on li emi o múlọ sinu ilẹ na nibiti o ti rè; irú-ọmọ rẹ̀ ni yio si ní i.
25. Njẹ awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani ngbé afonifoji: li ọla ẹ pada, ki ẹ si ṣi lọ si aginjù nipa ọ̀na Okun Pupa.