22. Agbo-ẹran tabi ọwọ́-ẹran ni ki a pa fun wọn, lati tó fun wọn ni? tabi gbogbo ẹja okun li a o kójọ fun wọn lati tó fun wọn?
23. OLUWA si sọ fun Mose pe, Ọwọ́ OLUWA ha kúru bi? iwọ o ri i nisisiyi bi ọ̀rọ mi yio ṣẹ si ọ, tabi bi ki yio ṣẹ.
24. Mose si jade lọ, o si sọ ọ̀rọ OLUWA fun awọn enia: o si pe ãdọrin ọkunrin ninu awọn àgba enia jọ, o si mu wọn duro yi agọ́ ká.
25. OLUWA si sọkalẹ wá ninu awọsanma, o si bá a sọ̀rọ, o si mú ninu ẹmi ti o wà lara rẹ̀, o si fi i sara awọn ãdọrin àgba na: o si ṣe, nigbati ẹmi na bà lé wọn, nwọn sì sọtẹlẹ ṣugbọn nwọn kò ṣe bẹ̃ mọ́.